Lyrics: Brymo – Okiki

Arìn ìrìn àjò mi ò m’aìdélé
Mo wọ̀lú, mo yà bàrà délé onínnkan
Ló bá ní n fobọ́, kí n tó wẹwọ, kí n tó jẹ iyán
Wọ́n ní n bẹṣu, kí ‘n tó yọfe, kí n tó m’ògùrọ̀

Balógun ló fẹ́ ṣoṣó dẹrú kó má ràn
Ó ló ju t’òhun lọ, kò ma rán
Ta ni baba tó bí mi l’ọmọ?
Ibo mo ti ṣè wá? Wà n ruga s’awọn

Àmọ́ o ràn (O ràn)
O ràn (O ràn)
O ràn, òkìkí mí ràn
O ràn (O ràn)
O ràn (O ràn)
O ràn, òkìkí mí ràn

Mo ronú títí, mo gbọ́rọ̀ tì, n ò lè paátì
Ẹni abíire ni mí, n ò lè fòdodo ṣawátì
Nṣe ni mo bò s’ọ̀nà, mo wọ sálubàtà, mo gẹ fìlà
Nṣe ni mo bò s’ọ̀nà, n ò rìn fìà-fìà, n ò ṣẹ fàlà-fàlà

Balógun ló fẹ́ ṣoṣó dẹrú kó má ràn
Ó ló ju t’òun lọ, kò ma rán
Ta ni baba tó bí mi l’ọmọ?
Ibo mo ti ṣè wá? Wà n ruga s’awọn

Àmọ́ o ràn (O ràn)
O ràn (O ràn)
O ràn, òkìkí mí ràn
O ràn (O ràn)
O ràn (O ràn)
O ràn, òkìkí mí ràn

Balógun ló fẹ́ p’òkòkí ẹlòmíràn
Ó ló ju t’òun lọ, kò ma rán
Pe ta ni baba tó bí mi l’ọmọ?
Ọ̀gbẹ̀rì lawo níwájú òrìṣà kò mọ

Àmọ́ o ràn
O ràn, o ràn
N ò fẹ́ òkìkí òmíràn
O ràn
O ràn
O ràn, òkìkí mí ràn


Posted

in

by

Tags:

Comments

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.